Àgbàlá Ìtàn Gbankogbi

Àgbàlá Ìtàn Gbankogbi � Words are my craft, stories are my magic. idasile agbala itan waye lati owo Oluwatobi Gbankogbi Ọrọ fun itesiwaju ASA ati EDE Yoruba

21/05/2025

Ija o dola oruko buruku lo so eni
Ma tori ija di arija gbaa eda
Mabinu abiju ranti wo eyin wo
Bi a ba pa oodun a kii pa oodun
Bi ija o gbani a si pani.

Majamasa la n mo akinkanju
Akin to mo ija ti o mosa
Iruwon ni ba ogun lo.
Pele laye gba, jeje loba irin ajo

Bi igi ba a da eye a fo loPele la fi pa amukuru peleMa tori oni gbagbe olaBi ewe ba a sun oko o pariFi jeje se ile ayeFi...
13/05/2025

Bi igi ba a da eye a fo lo
Pele la fi pa amukuru pele
Ma tori oni gbagbe ola
Bi ewe ba a sun oko o pari
Fi jeje se ile aye
Fi pele se pele
Awon to s'aye lana da
Won ti ku won ti lo.

Jeje layegba oremi.

ARAGBELAYEAye dabi oja ti opolopo iseda ti adeda da ni aworan ara re pelu eranko ati irufe orisirisi abemi ati ewebe  ti...
03/05/2025

ARAGBELAYE

Aye dabi oja ti opolopo iseda ti adeda da ni aworan ara re pelu eranko ati irufe orisirisi abemi ati ewebe ti n takuroso lol ipin won.

Ile aye gbooro dun langbalangba bi alagbalumu omi nitori adeada da ipin ni otooto ni ori o jo ori, ese o jo ese ti ika o dogba mo arawon. Bi alagbara se wa ni olola onipo n gbe ti eni ti kori Ile gbe lol janturu sugbon iwonba awon to ba ri aye ra lo gbe Inu oja ri tiwon ta.

Ile aye da bi oju ogun ti olomo ki i mo omo nitori ogun o dabi iyan. Olukuluku eda lo n sure arawon nitori imotara eni to bi eminikan mi o mo ti enikeni.

Bi eda o ba murasi igbiyan pelu aniyan lati ra aye Ile aye fun gbigbe, oungbogbo a dabi adagun omi nitori ARAGBELAYE.

29/06/2024

ORI ADETU A BI IWA PELE

Ori okere ku nitori ofin iwa inumi ni mo ri, ero inumi ni mo o mo tani yio mu mi.
Awon agba bo won ni omo ti a ba bawi to n'wa orun ki dandan yoo parun lojo kan.

Bi Ori okere se parun niyi nitori iwa aseju baba asete ti awon agba si so itan igbesi aye re si di owe ORI OKERE KOKO LAWO BI A BA WI FUN OMO ENI A GBO.

Leyin iku Ori Okere ninu igbo ebora, Ori Adetu sunkun pupo nitori adanu nla lo je lati fi igba omi eni se orun ajiyo, ki eni a fe dagbere mi o ni wa a mo nitori ofo nla ni ki i mojesin ti oju obi rorun alakeji.

Ori Adetu gbe oku Ori Okere lowo wo inu ilu pelu omije ti gbogbo tomode tagba si fi tilu tifon pade re lenu ibode. Bayi ni kabiesi se da ile ati ona re si meji fun Ori Adetu ti won si fi je oye Alagbala.

Ori Adetu Alagbala ntesiwa ninu iwa rere re leyin to pada si arin ilu ti opolopo si nwo awokose re fi huwa nitori bi eledumare se fi agbara, owo, ogun ati ipo da a lola ko fi ni enikeni lara tabi gbe iwa igberaga wo bi ewu. Bayi ni Ori Adetu se di eni aye'nfe ti ki i ni arun kankan.

Leyin opolopo odun ti alafia n'joba larin ilu ni kabiesi se aisan ranpe kan ti o si gba emi oba lo. Bi kabiesi se waja niyi ti awon agba si pe adifala lati wa difa omo oye tuntun. Bayi ni ifa se mu IWA OMO.

IWA OMO di oba tuntun gbogbo ilu n'jo won n'yo sugbon oro agba kan kii jabo ko ma ni ipa tie larin eda. Bi oruko omo se nro omo beni iwa eda ko le e gbe inu e fun ojo pipe lai hu jade bi ewebe.

IWA OMO joba tan ogbagbe adehun ofin ipilese ilu, o gba ade tan o se kan'ndu Kiri nitori agbara. Bi ara se n ni omode ni agba o ri ibi gbe orun le nitori ojoojumo ni ofin n'gori ofin.

Oba IWA OMO ranse pe Ori Adetu ko jawo ore sise nitori ilu oun kii se ilu akiikisore atipe oba lo ba lori oungbogbo, owo eru ni mo fe ki a maa fi awon eniyan wonyi se sugbon Ori Adetu dalohun pe laye olugbon ko baje besini laye aresa kobaje. Agba kiisi was loja kii ori Omo tuntun wo, iwa rere owo temi ko le kuro nitori apele oruko mi ni.

Inu bi kabiesi ti o si fi i ibinu kuro ni iwaju Ori Adetu. Bayi ni IWA OMO se n wa gbogbo ona lati reyin Ori Adetu. Gbogbo ilu feran Ori Adetu ju oba lo nitori awon agba bo won ni iwa omo lo n mu omo se okigbe gege bi oba IWA OMO alagbada iwa ika.

Leyin oran yi, kabiesi pa idi apo po pelu awon agba obayeje kan lati wa ona lati mu Ori Adetu nitori won ti gbiyanju gbogbo agbara won sungbon pabo lo n'jasi. Bi won se puro mo omo kansoso ti Ori Adetu bi niyii pe o ji ewu orisa gbe ti o si di ewo ilu pe enikeni ko gbodo da a*o iru e se oro.

Whala yi le pupo ti gbogbo ilu ti Ori Adetu n gbiyanju lati gba oromodiye won lowo iku ko gba pe omo re ko le hu iru iwa be. Bi gbogbo won se fi enu ko lati be ori omo Adetu si idi orisa niyii. Inu bi Ori Adetu gidigidi nitori enu to gbe leyin lotun pada ge e ge. Lotito Ori Adetu ni agbara lati koju ija ko gbogbo ilu na sugbon ki oro awon agba to so pe; ORI ADETU A BI IWA PELE le pada wa si imuse. Bi o se gbera niyi ti o si di odo to n san di oni oloni ti itan aye re si di manigbagbe larin awon alagbara ilu na.

ORI ADETU A BI IWA PELE.

Olukanju wola fola sile lo nile olaOlukanju wapo fi oro ipo pitanAja ti o sonu ko eti ikun si olodeOmode deete tan o n p...
01/07/2023

Olukanju wola fola sile lo nile ola
Olukanju wapo fi oro ipo pitan
Aja ti o sonu ko eti ikun si olode
Omode deete tan o n pariwo egbami
Iran eete kan kii b'awon gbe larin ilu
Igbo rere bayi ni ile alakeji...

Ona eburu sunmo tosi Ile sugbon bi o se yaara to bi asa lo fi n kanju gba aye lowo eni......

01/07/2023

Kosi igba ta'a*o ti o yeni laye. Adifa fun pele to fi suuru pon omo pelu oja lai kanju tu olu oran loju ona atila, nitori o mo pe ikanju oun pele ogbaa ogbaa l'ojasi.

Aku osu tuntun, ki ire tuntun ya Ile koowa wa lase Olodumare....

#

Oju dara tan inu dudu bi aroIfe oju wa di olori agba l'afinIfe oju lari kosi ninu ijinle iwaTa wa lo mo eni to f'enidenu...
29/06/2023

Oju dara tan inu dudu bi aro
Ife oju wa di olori agba l'afin
Ife oju lari kosi ninu ijinle iwa
Ta wa lo mo eni to f'enidenu
Ara l'amo ta lo o mo eni t'ofeni.....

29/06/2023

Ikanju oun pele ibikan ni n'jasi....

Rora sure nitori isubu ojiji...

Aku Ojumo oooo!!!

Address

Oyo
Oyo

Telephone

+2349067339199

Website

Alerts

Be the first to know and let us send you an email when Àgbàlá Ìtàn Gbankogbi posts news and promotions. Your email address will not be used for any other purpose, and you can unsubscribe at any time.

Contact The Business

Send a message to Àgbàlá Ìtàn Gbankogbi:

Share